Transcript GIRAMA
GBOLOHUN EDE YORUBA KIN NI GBOLOHUN? Gbolohun ni ipede ti o kun ti o ni oro-ise ti o si ni ise ti o n je. Gbolohun gbodo bere pelu leta nla, ki o si pari pelu ami idanuduro. Ona meji ni a le pin gbolohun si: 1. Ilana ihun 2. Ilana ilo IPINSOWOO GBOLOHUN NIPA IHUN Awon gbolohun abe ihun ni: 1. Gbolohun Alabode 2. Gbolohun onibo 3. Gbolohun Alakanpo 1. GBOLOHUN ALABODE: Eyi ni gbolohun ti a tun mo si gbolohun kukuru tabi gbolohun eleyo oro-ise. Apeere: Sade je isu. Apeja pa eja aro. 2. GBOLOHUN ONIBO: Eyi ni inu gbolohun ti a ti fi gbolohun kan bo inu gbolohun miiran. Apeere: Efo ti won ra ti gbo. O dara pe mo wa. 3. GBOLOHUN ALAKANPO: Inu gbolohun yii ni a ti fi oro-asopo so gbolohun meji po. Apeere: Mo lo si oja N ko ri ata ra = Mo lo si oja sugbon n ko ri ata.